Charleans Publication     
…… upholding the legacy

Current News Update In Yoruba - BBC Worldwide Service











News From The BBC

A Yoruba Perspective


Àwọn òṣìṣẹ́ ìlera wọ gau lórí ikú àwọn ọmọdé
Èèyàn mẹ́tàdínláàádọ́ta ni wọ́n kojú ìgbẹ́jọ́ ní Instabul lọ́sẹ̀ yìí. Èèyàn méjìlélógún lára àwọn tí wọ́n fẹ̀sùn kàn ló ti wà ní àhámọ́ òfin.

Ayédèrú ṣuga ti wà lọ́jà, ẹ fura – Ìjọba àpapọ̀ kìlọ̀
Ijagwu ni iwadii ajọ naa fihan pe awọn suga yii ni wọn ko ni orukọ lara , wọn ko ni ọjọ ti wọn sẹda rẹ lara ati ọjọ ti yoo bajẹ.

Simon Ekpa, olórí ẹgbẹ́ agbésùnmọ̀mí IPOB dèrò àtìmọ́lé ní Finland
Igba akọkọ ti wọn mu ni inu oṣu keji ọdun 2023 amọ wọn fi silẹ lẹyin wakati diẹ.

Gbogbo ọ̀nà ni Yinka Ayefle fi ní ipa rere lórí mi, àmọ́ kò túmọ̀ sí pé mi ò ní ìpèníjà – Laolu Ayefele
Lara awọn ipenija Laolu ni bi awọn eyan ṣe maa n fi oju ọlọrọ wo o latari pe o jẹ aburo Yinka Ayefele.

Mo ní láti lúwẹ̀ẹ́ lọ gbé àwọn èèyàn kúrò nílé wọn lásìkò omíyalé
Ni oṣu kinni, ọfisi ajọ isọkan agbaye gbe atẹjade kan sita lori oju ọjọ ati irinna awọn eeyan, ṣalaye ti igbesẹ ko ba waye, o ṣeese ki ilẹ riri waye ni ọdun 2050.

Ọlọ́pàá Amẹrika yìnbọn pa ọkùnrin tó pe 911 fún ìrànlọ́wọ́
Agbẹjọro ọlọpaa ti wọn fẹsun ipaniyan naa kan ti sọ pe onibara oun ko wu iwa ọdaran kankan.

Ìwà ọ̀daràn tó ń wáyé nípasẹ̀ kíkó pàǹtí lọ sílẹ̀ òkèrè
Àjọ ìṣọ̀kan àgbáyé ní ìdá mẹ́ẹ̀dógún péré nínú àwọn ìdọ̀tí tó wà káàkiri àgbáyé ni wọ́n ń ṣe àtúnlò rẹ̀ àti pé ọ̀pọ̀ àwọn iléeṣẹ́ ló máa ń wá ọ̀nà ẹ̀bùrú láti fi da àwọn ilẹ̀ wọn nù.

Ipa tí ìpìnnu ìjọba lórí owó orí yóò ní lára mẹ̀kúnnù Naijiria rèé
Awọn nnkan jijẹ, ohun lilo bii ina ọba, itọju ailera, eto ẹkọ, sisan owo ile, lilo foonu ati bẹẹ bẹẹ lọ ti di iṣọro bayii nitori atunto ti iṣakoso Aarẹ Tinubu gunle.

Lẹ́yìn tí UK àti Canada ba ojú ọ̀pọ̀lọpọ̀ jẹ́, wo orílẹ̀-èdè márùn-ún tí o le Japa sí nírọ̀rùn
Akojọpọ marun-un lara awọn orilẹ-ede ti o le fi ṣe ibugbe gẹgẹ bi ọmọ Naijiria

Afẹ́fẹ́ ìdọ̀tí, kùrukùru àti oòrùn yóò gba ojú ọjọ́ láti Ọjọ́rú
Gẹgẹ bi wọn Nimet ṣe wi, kaakiri Naijiria ni ayipada naa yoo ti waye.

Ìdí tí ìjọ Katoliiki ní Kenya ṣe kọ $40,000 tí Aarẹ Ruto fun wọn
Bi a ba ṣi owo yii ni pọn-un, iye rẹ ni (£32,000). To ba si jẹ Naira, o din diẹ ni aadọrin miliọnu ni, #66,721,200.00 lo jẹ.

Ataoja ìlú Oṣogbo, Ọba Jimoh Olanipekun, sọ̀rọ̀ lórí àwọn tó ṣe ìwọ́de pé kó fi ipò sílẹ̀
Awọn eeyan kan niluu Osogbo dide lodi si Oba Jimoh Olanipekun

Àwọn agbébọn dáná sun oko, wọ́n tún jí ọ̀pọ̀ èèyàn gbé lọ
Àwọn olùgbé ìlú náà tó wà lẹ́bàá ẹnubodè ìpínlẹ̀ Kebbi ní àdánù ńlá ni àwọn agbébọn ọ̀hún kó bá ọrọ̀ ajé àwọn tó sì jẹ́ káwọn pàdánù èrè oko bíi àgbàdo, òwú, ẹ̀wà àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Ojúṣe taa ni láti pàárọ̀ mítà tó gbó tàbí bàjẹ́ ní Naijiria?
Àtẹ̀jáde kan tí NERC fi sórí ìkànnì X wọn sọ pé bí àwọn iléeṣẹ́ DISCO ọ̀hún ṣe ní káwọn oníbàárà wá san owó láti gba mítà mìíràn lòdì sí àdéhùn tí wọ́n tọwọ́bọ̀.

Ẹ yé lo fọ́tò ìhòhò àwọn ọmọdé pawó lórí ayélujára, àwọn òbí ọmọkùnrin tó gbẹ̀mí ara rẹ́ kìlọ̀
Baba ati iya Murray di ẹbi iku rẹ ru awọn ileeṣẹ itakun ayelujara wi pẹ ẹjẹ wa lọwọ wọn tori wọn o maa daabo bo awọn ọdọmọde to lori ayelujara.

Mọ̀ nípa bí o ṣe le dá ààbò bo ara a rẹ lọ́wọ́ àwọn àjálù tó le wáyé nínú balùwẹ̀
Yatọ si yíyọ ṣubu, ọpọ awọn kokoro ti a foju ri lo wa ninu baluwẹ ti wọn si le se ijamba lara eeyan.

Sunday Babatunde, eégún oníná l'Ogbomọṣọ, Danafojura, jáde l'áyé
Awọn ẹbi oloogbe naa fidi rẹ mulẹ pe nile iwosan ẹkọṣẹ iṣegun fasiti Bowen, BUTH, niluu Ogbomoso ni ọkunrin naa dakẹ si.

Àwọn kókó ọ̀rọ̀ Tinubu lórí ìgbógun ti ebi àti ìṣẹ́ níbi àpérò ‘G20 Summit' ní Brazil
Aarẹ Tinubu sọ nibi ipade naa wi pe igbesẹ ijọba orilẹede Brazil lati gbogun ti ebi ati iṣẹ lagbaaye jẹ ọna kan gboogi lati wa ojutuu si ọkan lara iṣoro to n koju gbogbo agbaye bayii.

Kí ni èrè tí Naijiria lè jẹ lára àpérò 'G20 Summit' tí Tinubu lọ fún ní Brazil?
Gẹgẹ bi ileeṣẹ to n ri si ọrọ ilẹ okeere ṣe ṣalaye, bi Tinubu ṣe fẹẹ kopa ninu ipade naa yoo ro Naijiria lagbara lati le dI ojulowo ọmọ ẹgbẹ G20.

Àjọ DSS gbé Ladi Adebutu sí àhámọ́
Akọwe ẹgbẹ naa nipinlẹ Ogun, Kayode Adebayo lo fidi iṣẹlẹ naa mulẹ ninu atẹjade kan to fi síta lọjọ Aje.

Gbígba abẹ́rẹ́ àjẹsára láti dènà Monkeypox gbérasọ ní Nàìjíríà
Nàìjíríà ni orílẹ̀ èdè kẹta nílẹ̀ Áfíríkà, lẹ́yìn Rwanda àti Democratic Republic of Congo (DR Congo), tí yóò bẹ̀rẹ̀ sí ní fún àwọn èèyàn ní abẹ́rẹ́ ajẹsára Monkeypox.

Wo yàrá tí Sango Olukoso gbé ní ìlú Igbeti àti ìwádìí BBC Yorùbá nípa rẹ̀
Ileeṣẹ BBC News Yoruba ṣe abẹwo si ilu Igbeti lati mọ nipa itan to tan mọ Alaafin Sango ati ibaṣepọ rẹ pẹlu Ilu Igbeti.

Kókó mẹ́rin tó jẹyọ nínú àbẹ̀wò olóòtú ìjọba India, Narenda Modi, si Tinubu
Ilu Abuja ni ọrọ ileri naa ti waye laaarin Aarẹ Bola Tinubu ati Olootu ijọba ilẹ India, Narenda Modi, ẹni to ṣabẹwo si Naijiria ati Tinubu.

PDP kọ èsì ìbò gómìnà tí INEC kéde nípìnlẹ̀ Ondo, wọ́n ní ìdìbò kò wáyé l'áwọn ibì kan
Egbẹ oṣelu PDP ni oun yoo lọ sile ẹjọ lori esi idibo ọhun ninu eyi ti oludije wọn Agboola Ajayi ti fidirẹmi.

Kókó nípa Lucky Aiyedatiwa tó wọlé ìbò gómìnà ìpínlẹ̀ Ondo
Ni bayii, Aiyedatiwa ti di ojulowo gomina to lẹtọọ si ọdun mẹrin lori aleefa gẹgẹ bii gomina adiboyan nipinlẹ Ondo.

Gómìnà tí wọ́n dìbò yàn nípìnlẹ̀ Ondo, Lucky Aiyedatiwa, bá aráàlú sọ ọ̀rọ̀ àkọ́sọ
Gomina Lucky Aiyedatiwa ba araalu sọrọ

Lucky Aiyedatiwa olùdíje ẹgbẹ́ òṣèlú APC wọlé ìbò gómìnà ìpínlẹ̀ Ondo
Lapapọ ibo 366,781 ni Aiyedatiwa ri nigba ti Agboola oludije PDP to ṣe ipo keji ninu eto idibo naa ri 117,845.

Wo iye ìbò tí olùdíje kọ̀ọ̀kan ní láwọn ìjọba ìbílẹ̀ nínú ìbò gómìnà ìpínlẹ̀ Ondo
Bo si tilẹ jẹ pe oludije mejidinlogun lo kopa kaakiri awọn ẹgbẹ oṣelu to wa, esi to n jade fi han pe laaarin APC ati PDP nikan ni onka to lapẹẹẹrẹ ti waye.

Ṣé lóòótọ́ nílé ẹjọ́ fagilé ìbò MC Oluomo gẹ́gẹ́ ààrẹ ẹgbẹ́ NURTW ní Naijiria?
Lana ọjọ Abamẹta ni iroyin kan jade eyi to sọ pe ile ẹjọ kotẹmilọrun niluu Abuja ti fagile eto idibo to gbe Alhaji Musiliu Akinsanya ti ọpọ mọ si MC Oluomo wọle gẹgẹ bi aarẹ ẹgbẹ onimọto, NURTW.

Bí Chdinma Adetshina, ọmọ Naijiria ṣe ṣe ipò Kejì ní ìdíje Miss Universe 2024
Bi idije Miss Universe 2024 ṣe lọ

Ààrẹ Tinubu fi àmì ẹ̀yẹ tó ga dá Olóògbé Ọ̀gágun Lagbaja lọ́lá
Oludamọran Aarẹ Bola Tinubu lori eto iroyin, Bayo Onanuga lo kede iku ọgagun naa naa ninu atẹjade kan to fi sita lọjọ kẹfa oṣu Kọkanla ọdun yii.

Ilé alájà mẹ́rin dàwó, wọ́n ń gba inú ihò fáwọn tó há s’ábẹ́ lomí mu
Wọn ni awọn n gba ibi iho kan fi afẹfẹ eemi ranṣẹ si wọn pẹlu, ati iyẹfun glucose to n ro ni lagbara.

'Kí a tó lọ “Studio” lọ kọ orin “Odun nlo sopin”, a ju ara wa sínú àdúrà, bíbélì, ìmísí, ...'
Adari ẹgbẹ akọrin to kọrin ọdun n lọ sopin, Mama D.O Fasoyin ba BBC Yoruba sọrọ lori agbekalẹ orin naa.

Mọ̀ nípa ohun tó ṣokùnfà ikú gbajúmọ̀ òṣèré tíátà krìstẹ́nì Korede Are ‘Baba Gbenro’
Iyalẹnu nla ni iku Baba Gbenro jẹ fun ọpọlọpọ eeyan nigba ti iroyin iku rẹ jade l’Ọjọbọ.




Event Info

Click Here To See Info

1

Date: 2017-03-11

2

Openning Time: 6pm

3

Venue: Banquet Hall, Premier Hotel, Ibadan




Special Guest List

Click Here To See List

1

Distinquished Guest Of Honour: Bashorun Rotimi Obeisun

2

Special Guest Of Honour: Alhaji Olalekan Alli

3

Guest Of Honour: Bimbo Kolade

4

Father Of The Day: Prof B.B Adeleke

5

Chairman Of The Day: Majek Okunola OWOO









Share This Info

Click To See Info To Share

Enter the email address to send a link of this page to and submit

Social Networks

Share this info with your favourite social network



Copy And Paste

Copy the Link and paste anywhere on the web to promote